Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Sáàmù 106:35-48 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

35. Ṣùgbọ́n wọn dàpọ̀ mọ́ àwọn orílẹ̀ èdè,wọ́n sì gbà láti ṣe bí àṣà wọn

36. Wọ́n sì sin àwọn òrìṣà wọntí o di ìkẹ́kùn fún wọn.

37. Wọ́n fi àwọn ọmọkùnrin wọn rúbọàti àwọn ọmọbìnrin fún òrìsà.

38. Wọn ta ẹ̀jẹ̀ aláìṣẹ̀ sílẹ̀.Ẹ̀jẹ̀ àwọn ọmọkùnrin àti àwọnọmọbìnrin wọn.Wọn fi wọ́n rúbọ sí ère Kénánì, ilẹ̀ náà sì di àìmọ́ fún ẹ̀jẹ̀

39. Wọn si fi ìṣe ara wọn sọ arawọn di aláìmọ́, wọ́n sì ṣepanṣágà lọ pẹ̀lú iṣẹ́ wọn.

40. Nígbà náà Olúwa bínú sí àwọn ènìyàn Rẹ̀ó sì kórìíra àwọn ènìyàn Rẹ̀

41. Ó sì fà wọ́n lé àwọn orílẹ̀ èdè lọ́wọ́,àwọn ọ̀tá wọn sì jọba lórí wọn.

42. Àwọn ọ̀tá wọn sì ń pọ́n wọ́n lójúwọn sì mú wọn sìn lábẹ́ àṣẹ wọn.

43. Ní ọ̀pọ̀ ìgbà òun gbà wọ́n,Ṣíbẹ̀ wọ́n si ń ṣọ̀tẹ̀ sí ìwọ́n sì sòfò dànù nínú ẹ̀ṣẹ̀ wọn.

44. Ṣùgbọ́n o kíyèsí wọn nítorí ìṣòronígbà tí ó gbọ́ ẹkún wọn;

45. Ó rántí májẹ̀mú Rẹ̀ nítorí wọnNítorí agbára ìfẹ́ Rẹ̀, ó ṣàánú wọn.

46. Lójú gbogbo àwọn tí o kó wọn ní ìgbèkùnó mú wọn rí àánú.

47. Gbà wá, Olúwa Ọlọ́run wa,kí o sì ṣà wá jọ kúrò láàrin àwọn aláìkọlàláti máa fí ọpẹ́ fún orúkọ mímọ́ Rẹláti máa ṣògo nínú ìyìn Rẹ.

48. Olùbùkún ni Olúwa,Ọlọ́run Ísírẹ́lì, láti ìrandíranJẹ́ kí gbogbo ènìyàn kí ó wí pé, “Àmín!”Ẹ fi ìyìn fún Olúwa!

Ka pipe ipin Sáàmù 106