Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Sáàmù 106:22-42 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

22. Iṣẹ́ ìyanu ní ilẹ̀ Ámùàti ohun ẹ̀rù ni ẹ̀bá òkun pupa

23. Bẹ́ẹ̀ ní, ó sọ wí pé oun yóò pa wọ́n runbí kò ba ṣe tí Mósè, tí ó yàn,tí ó dúró níwájú ẹ̀yà náàtí ó pa ìbínú Rẹ̀ mọ́ láti má pa wọ́n run mọ́

24. Nígbà náà, wọn kẹ́gàn ilẹ̀ dídára náàwọn kò gba ilérí Rẹ̀ gbọ́.

25. Wọn ń kùn nínú àgọ́ wọnwọn kò sì gbọ́ràn sí Olúwa.

26. Bẹ́ẹ̀ ni ó gbé ọwọ́ Rẹ̀ sókè sí wọnkí òun le jẹ́ kí wọn ṣubú nínú ihà,

27. Láti jẹ́ kí àwọn ọmọ Rẹ̀ ṣubú lára orílẹ̀ èdèláti fọ́nu wọn káàkiri lórí ilẹ̀.

28. Wọn dá ara wọn pọ̀ mọ́ Baali-Péórù,wọn sì ń jẹ ẹbọ ti a rú sí àwọn òkú òrìṣà

29. Wọ́n mú Ọlọ́run bínú pẹ̀lú ohun búburú tí wọn ń ṣeàjàkálẹ̀-àrùn jáde láàrin wọn.

30. Ṣùgbọ́n Fínéhásì dìde láti dá sí i,àjàkálẹ̀-àrùn náà sì dáwọ́ dúró lọ́gán

31. A sì ka èyí sí òdodo fún un àtifún àwọn ìrandíran tí ń bọ̀

32. Níbi omi Méríbà, wọn bí Ọlọ́run nínú,ohun búburú wá sí orí Mósè nítorí wọn.

33. Nítorí tí wọ́n ṣọ̀tẹ̀ sí ẹ̀mí Ọlọ́run.Ọ̀rọ̀ àìdára sì ti ẹnu Mósè wá.

34. Wọn kò pa àwọn ènìyàn rungẹ́gẹ́ bí Ọlọ́run tí sọ fún wọn,

35. Ṣùgbọ́n wọn dàpọ̀ mọ́ àwọn orílẹ̀ èdè,wọ́n sì gbà láti ṣe bí àṣà wọn

36. Wọ́n sì sin àwọn òrìṣà wọntí o di ìkẹ́kùn fún wọn.

37. Wọ́n fi àwọn ọmọkùnrin wọn rúbọàti àwọn ọmọbìnrin fún òrìsà.

38. Wọn ta ẹ̀jẹ̀ aláìṣẹ̀ sílẹ̀.Ẹ̀jẹ̀ àwọn ọmọkùnrin àti àwọnọmọbìnrin wọn.Wọn fi wọ́n rúbọ sí ère Kénánì, ilẹ̀ náà sì di àìmọ́ fún ẹ̀jẹ̀

39. Wọn si fi ìṣe ara wọn sọ arawọn di aláìmọ́, wọ́n sì ṣepanṣágà lọ pẹ̀lú iṣẹ́ wọn.

40. Nígbà náà Olúwa bínú sí àwọn ènìyàn Rẹ̀ó sì kórìíra àwọn ènìyàn Rẹ̀

41. Ó sì fà wọ́n lé àwọn orílẹ̀ èdè lọ́wọ́,àwọn ọ̀tá wọn sì jọba lórí wọn.

42. Àwọn ọ̀tá wọn sì ń pọ́n wọ́n lójúwọn sì mú wọn sìn lábẹ́ àṣẹ wọn.

Ka pipe ipin Sáàmù 106