Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Sáàmù 106:15-19 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

15. Nígbà náà, ó fún wọn ní ohun tí wọ́n bèèrè fúnṣùgbọ́n ó rán àìsàn búburú sí wọn.

16. Nínú ibùdó ni wọ́n ṣe ìlara Mósèpẹ̀lú Árónì, ẹni tí ó jẹ́ mímọ́ sí Olúwa.

17. Ilẹ̀ la ẹnu ó sì gbé Dátanì mìó bo ẹgbẹ́ Àbìrámù mọ́lẹ̀

18. Ọwọ́ iná yọ ní ẹgbẹ́ àwọn ọmọ ẹ̀yin Rẹ̀;iná jo àwọn ènìyàn búburú.

19. Ní Hórébù wọ́n ṣe ẹ̀gbọ̀rọ̀ màlúùwọn sì sin òrìṣà tí a ṣe láti ara ìrìn.

Ka pipe ipin Sáàmù 106