Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Sáàmù 106:1-18 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

1. Yin Olúwa Ẹ fi ìyìn fún Olúwa, nítorí tí o ṣeun.Ẹ fi ọpẹ́ fún Olúwa nítorí tí ó ṣeun;Nítorí tí ìfẹ́ Rẹ̀ dúró láéláé.

2. Ta ni ó le ròyìn iṣẹ́ agbára Olúwata ni lè sọ nípa ìyìn Rẹ̀?

3. Ìbùkún ni fún àwọn tí ń pa ìdájọ́ mọ́?Ẹni tí tí ń ṣe ohun tí ó tọ́

4. Rántí mi, Olúwa,Nígbà tí ó bá fi ojú rere Rẹ̀ hàn,wá sí ìhà mi nígbà tí ìwọ bá gbà wọ́n,

5. Kí èmi kí ó lè jẹ ìgbádùn àlàáfíà àwọn tí ìwọ ti yànkí èmi kí ó sì darapọ̀ mọ́ àwọn ènìyànìní Rẹ láti jọ yìn ọ́ lógo.

6. Àwa ti dẹ́sẹ̀ gẹ́gẹ́ bí àwọn baba wa ti ṣeàwa ti ṣe ohun tí kò dá aa sì ti hùwà búburú

7. Nígbà tí àwọn baba wa wà ní Éjíbítìiṣẹ́ ìyanu Rẹ kò yé wọnwọn kò rántí ọ̀pọ̀lọpọ̀ àánú Rẹgẹ́gẹ́ bí wọn ṣe sọ̀tẹ̀ sí ọ níbi òkun, àní nibi òkun pupa

8. Ṣùgbọ́n o gbà wọ́n là nítorí orúkọ Rẹláti jẹ́ kí agbára ńlá Rẹ di mímọ̀

9. O bá òkun pupa wí, ó sì gbẹ;o sì mú wọn la ìbú já bí ihà

10. O gbà wọ́n là kúrò lọ́wọ́ àwọn ọ̀tá wọnláti ọwọ́ ọ̀tá ni ó ti gbà wọ́n

11. Omi ya lu àwọn ọ̀tá wọn, bẹ́ẹ̀ nikò sí èyí tí ó yè nínú wọn.

12. Nígbà náà wọn gba ìpínnú Rẹ gbọ́wọ́n sì kọrin ìyìn Rẹ.

13. Ṣùgbọ́n wọn kò pẹ́ gbàgbé ohun tí o ṣewọn kò sí dúró gba ìmọ̀ràn Rẹ

14. Nínú ihà ni wọn tí ṣe ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́nínú aṣálẹ̀ wọn dán Ọlọ́run wò

15. Nígbà náà, ó fún wọn ní ohun tí wọ́n bèèrè fúnṣùgbọ́n ó rán àìsàn búburú sí wọn.

16. Nínú ibùdó ni wọ́n ṣe ìlara Mósèpẹ̀lú Árónì, ẹni tí ó jẹ́ mímọ́ sí Olúwa.

17. Ilẹ̀ la ẹnu ó sì gbé Dátanì mìó bo ẹgbẹ́ Àbìrámù mọ́lẹ̀

18. Ọwọ́ iná yọ ní ẹgbẹ́ àwọn ọmọ ẹ̀yin Rẹ̀;iná jo àwọn ènìyàn búburú.

Ka pipe ipin Sáàmù 106