Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Sáàmù 105:36-45 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

36. Nígbà náà, ó kọlu gbogbo àwọn ilẹ̀ wọn,ààyò gbogbo ipá wọ́n.

37. Ó mú Ísírẹ́lì jádeti òun ti fàdákà àti wúrà,nínú ẹ̀yà Rẹ̀ kò sí aláìlera kan.

38. Inú Éjíbítì dùn nígbà tí wọn ń lọ,nítorí ẹ̀rù àwọn Ísírẹ́lí ń bá wọ́n.

39. Ó ta awọsánmọ̀ fún ìbòrí,àti iná láti fún wọn ni ìmọ́lẹ̀ lálẹ́

40. Wọn bèèrè, ó sì mú ẹyẹ àparò wá,ó sì fi oúnjẹ ọ̀run tẹ́ wọ́n lọ́rùn.

41. Ó sì la àpáta, ó sì mú omi jáde;gẹ́gẹ́ bí odò tí ń ṣàn níbi gbígbẹ.

42. Nítorí ó rántí ìlérí mímọ́ Rẹ̀àti Ábúráhámù ìránṣẹ́ Rẹ̀.

43. Ó sì fi ayọ̀ mú àwọn ènìyàn Rẹ̀ jádepẹ̀lú ayọ̀ ní ó yan àyànfẹ́ Rẹ̀

44. Ó fún wọn ní ilẹ̀ ìní náà,wọn sì jogún iṣẹ́ àwọn ènìyàn náà,

45. Kí wọn kí ó le máa pa àṣẹ Rẹ̀ mọ́kí wọn kí ó le kíyèsí òfin Rẹ̀.Ẹ fi ìyìn fún Olúwa.

Ka pipe ipin Sáàmù 105