Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Sáàmù 105:1-6 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

1. Ẹ fi ọpẹ́ fún Olúwa, ké pe orukọ Rẹ̀:Jẹ́ kí a mọ ohun tí ó ṣe láàrin àwọn orílẹ̀ èdè;

2. Kọrin sí i, kọrin ìyìn sí i;sọ ti iṣẹ́ ìyanu Rẹ̀ gbogbo.

3. Ṣògo nínú orúkọ mímọ́ Rẹ̀:Jẹ́ kí ọkàn àwọn tí ń wá Olúwa kí ó yọ̀.

4. Wá Olúwa àti ipá Rẹ̀;wa ojú Rẹ̀ nígbà gbogbo.

5. Rantí àwọn ìyanu tí ó ti ṣe,ìyanu Rẹ̀, àti ìdájọ́ tí ó sọ,

6. Ẹ̀yin ìran Ábúráhámù ìránṣẹ́ Rẹ̀,ẹ̀yin ọmọkùnrin Jákọ́bù, àyànfẹ́ Rẹ̀.

Ka pipe ipin Sáàmù 105