Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Sáàmù 105:1-18 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

1. Ẹ fi ọpẹ́ fún Olúwa, ké pe orukọ Rẹ̀:Jẹ́ kí a mọ ohun tí ó ṣe láàrin àwọn orílẹ̀ èdè;

2. Kọrin sí i, kọrin ìyìn sí i;sọ ti iṣẹ́ ìyanu Rẹ̀ gbogbo.

3. Ṣògo nínú orúkọ mímọ́ Rẹ̀:Jẹ́ kí ọkàn àwọn tí ń wá Olúwa kí ó yọ̀.

4. Wá Olúwa àti ipá Rẹ̀;wa ojú Rẹ̀ nígbà gbogbo.

5. Rantí àwọn ìyanu tí ó ti ṣe,ìyanu Rẹ̀, àti ìdájọ́ tí ó sọ,

6. Ẹ̀yin ìran Ábúráhámù ìránṣẹ́ Rẹ̀,ẹ̀yin ọmọkùnrin Jákọ́bù, àyànfẹ́ Rẹ̀.

7. Òun ni Olúwa Ọlọ́run wa:ìdájọ́ Rẹ̀ wà ní gbogbo ayé.

8. Ó rántí májẹ̀mú Rẹ̀ láéláé,ọ̀rọ̀ tí ó páláṣẹ, fún ẹgbẹgbẹ̀rún ìran;

9. Májẹ̀mu tí ó ṣe pẹ̀lú Ábúráhámù,àti ìbúra tí ó búra fún Ísáákì.

10. Ó fi da Jákọ́bù lójú gẹ́gẹ́ bí àṣẹsí Ísírẹ́lì gẹ́gẹ́ bi májẹ̀mú ayérayé

11. “Fún ìwọ ní èmi ó fún ní ilẹ̀ Kénánìgẹ́gẹ́ bí ìpín tí ìwọ ó jogún”.

12. Nígbà tí wọn kéré níye,wọn kéré jọjọ, àti àwọn àjòjì níbẹ̀

13. Wọn ń lọ láti orílẹ̀ èdè sí orílẹ̀ èdè,láti ìjọba kan sí òmìrán.

14. Kò gba ẹnikẹ́ni láàyè láti pọ́n wọn lójú;ó fi ọba bú nítorí tí wọn:

15. “Má ṣe fọwọ́ kan ẹni àmì òróró mi,má sì ṣe wòlíì mi nibi.”

16. Ó pe ìyàn sórí ilẹ̀ náàó sì pa gbogbo ìpèṣè oúnjẹ wọn run;

17. Ó sì rán ọkùnrin kan ṣíwájú wọnJósẹ́fù tí a tà gẹ́gẹ́ bí ẹrú.

18. Wọn fi sẹkẹ́sẹkẹ̀ bọ ẹsẹ̀ Rẹ̀a gbé ọrùn Rẹ̀ sínú irin

Ka pipe ipin Sáàmù 105