Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Sáàmù 104:5-11 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

5. O fi ayé gúnlẹ̀ lórí àwọn ìpìlẹ̀;tí a kò le è mi láéláé.

6. Ìwọ fi ibú omi bò ó mọ́lẹ̀ bí aṣọ;àwọn omi sì dúró lórí àwọn òkè ńlá.

7. Ṣùgbọ́n nípa ìbáwí Rẹ ni àwọn omi lọ,nípa ohùn àrá Rẹ ni wọ́n sálọ;

8. Wọn ṣàn kọjá lórí àwọn òkè,wọn sọ̀kalẹ̀ lọ sí àwọn pẹ̀tẹ́lẹ̀,sí ibi tí ìwọ ti yàn fún wọn.

9. Ìwọ gbé òpin tí wọn kò le kọjá Rẹ̀ kálẹ̀;láéláé ní wọ́n kò ní lé bo ayé mọ́lẹ̀ lẹ́ẹ̀kan síi.

10. Ìwọ mú kí ìsun da omi sí àwọn àfonífojì;tí ó ń ṣàn láàrin àwọn òkè.

11. Wọn fún gbogbo àwọn ẹranko igbó ní omiàwọn kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ ń pa òùngbẹ wọn.

Ka pipe ipin Sáàmù 104