Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Sáàmù 104:27-35 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

27. Àwọn wọ̀nyí ń wò ọ́láti fún wọn ní oúnjẹ wọn lákòókò Rẹ̀.

28. Nígbà tí ìwọ bá fi fún wọn,wọn yóò kó o jọ;nígbà tí ìwọ bá là ọwọ Rẹ̀,a tẹ́ wọn lọ́rùn pẹ̀lú ohun rere.

29. Nígbà tí ìwọ bá pa ojú Rẹ mọ́ara kò rọ̀ wọ́nnígbà tí ìwọ bá mú ẹ̀mí wọn lọ,wọn ó kú, wọn o sì padà sí erùpẹ̀.

30. Nígbà tí ìwọ rán ẹ̀mí Rẹ,ní a dá wọn,ìwọ sì tún ojú ayé ṣe.

31. Jẹ́ kí ògo Olúwa wà pẹ́ títí láé;kí inú Olúwa kí ó dùn ní ti iṣẹ́ Rẹ̀

32. Ẹni tí ó wo ayé, tí ó sì wárìrì,ẹni tí ó fọwọ́ tọ́ àwọn òkè, tí wọ́n yọ èéfín.

33. Ní gbogbo ayé mí ní ń ó kọrin sí Olúwa:èmi ó kọrin ìyìn sí Olúwaníwọ̀n ìgbà tí mo wà láàyè.

34. Jẹ́ kí ẹ̀kọ́ mi kí ó tẹ ọ lọ́rùnbí mo tí ń yọ̀ nínú Olúwa.

35. Ṣùgbọ́n kí ẹlẹ́sẹ̀ kúrò láyékí ènìyàn búburú má sì sí mọ́.Yin Olúwa, ìwọ ọkàn mi.Yin Olúwa.

Ka pipe ipin Sáàmù 104