Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Sáàmù 103:6-21 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

6. Olúwa ń ṣe òdodo àti ìdájọ́ fúngbogbo àwọn tí a nilára.

7. Ó fi ọ̀nà Rẹ̀ hàn fún Mósè, iṣẹ́ Rẹ̀ fun àwọn ọmọ Ísírẹ́lì;

8. Olúwa ni aláàánú àti olóore,ó lọ́ra láti bínú, ó sì pọ̀ ní ìfẹ́.

9. Òun kì í bá ni wí ní ìgbà gbogbobẹ́ẹ̀ ni kì í pa ìbínú Rẹ mọ́ láéláé;

10. Òun kì í ṣe sí wá gẹ́gẹ́ bí ẹ̀ṣẹ̀ wabẹ́ẹ̀ ni kì í san-án fún wa gẹ́gẹ́bí àìṣedédé wa.

11. Nítorí bí ọ̀run ṣe ga sílẹ̀,bẹ́ẹ̀ ni ìfẹ́ Rẹ̀ tóbi sí àwọn tí ó bẹ̀rù Rẹ̀.

12. Bí ìlà òòrùn ti jìnnà sí ìwọ̀ òòrunbẹ́ẹ̀ ní ó ṣe mú ìrékọjá wá jìnnà sí wa.

13. Bí bàbá ti ń ṣe ìyọ́nú sí àwọn ọmọ Rẹ̀,bẹ́ẹ̀ ni Olúwa ń ṣe ìyọ́nú sí àwọn tí ó bẹ̀rù Rẹ̀;

14. Nítorí tí ó mọ dídá wa,ó rántí pé erùpẹ̀ ni wá.

15. Bí ó ṣe ti ènìyàn ni, ọjọ́ Rẹ̀ dà bí koríko,ó gbilẹ̀ bí ìtànnà ewéko ìgbẹ́;

16. Afẹ́fẹ́ fẹ́ kọjá lọ lórí Rẹ̀,kò sì rántí ibùjókòó Rẹ̀ mọ́.

17. Ṣùgbọ́n láti ayé rayé ni ìfẹ́ Olúwa ti wà pẹ̀lú àwọn tí ó bẹ̀rù Rẹ̀,àti òdodo Rẹ̀ wà láti ọmọ dé ọmọ

18. Sí àwọn tí ó pa májẹ̀mú Rẹ̀ mọ́àti àwọn tí ó rántí òfin Rẹ̀ láti ṣe wọ́n.

19. Olúwa ti pèsè ìtẹ́ Rẹ̀ nínú ọ̀run,ìjọba Rẹ̀ ní ó sì borí ohun gbogbo.

20. Yin Olúwa, ẹ̀yin ańgẹ́lì Rẹ̀ tí ó ní ipá,tí ó pa òfin ọ̀rọ̀ Rẹ̀ mọ́

21. Yin Olúwa, ẹ̀yin ogun ọ̀run Rẹ̀ gbogbo,ẹ̀yin ìránṣẹ́ Rẹ̀ tí ń ṣe ìfẹ́ Rẹ̀.

Ka pipe ipin Sáàmù 103