Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Sáàmù 103:13-17 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

13. Bí bàbá ti ń ṣe ìyọ́nú sí àwọn ọmọ Rẹ̀,bẹ́ẹ̀ ni Olúwa ń ṣe ìyọ́nú sí àwọn tí ó bẹ̀rù Rẹ̀;

14. Nítorí tí ó mọ dídá wa,ó rántí pé erùpẹ̀ ni wá.

15. Bí ó ṣe ti ènìyàn ni, ọjọ́ Rẹ̀ dà bí koríko,ó gbilẹ̀ bí ìtànnà ewéko ìgbẹ́;

16. Afẹ́fẹ́ fẹ́ kọjá lọ lórí Rẹ̀,kò sì rántí ibùjókòó Rẹ̀ mọ́.

17. Ṣùgbọ́n láti ayé rayé ni ìfẹ́ Olúwa ti wà pẹ̀lú àwọn tí ó bẹ̀rù Rẹ̀,àti òdodo Rẹ̀ wà láti ọmọ dé ọmọ

Ka pipe ipin Sáàmù 103