Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Sáàmù 103:12-16 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

12. Bí ìlà òòrùn ti jìnnà sí ìwọ̀ òòrunbẹ́ẹ̀ ní ó ṣe mú ìrékọjá wá jìnnà sí wa.

13. Bí bàbá ti ń ṣe ìyọ́nú sí àwọn ọmọ Rẹ̀,bẹ́ẹ̀ ni Olúwa ń ṣe ìyọ́nú sí àwọn tí ó bẹ̀rù Rẹ̀;

14. Nítorí tí ó mọ dídá wa,ó rántí pé erùpẹ̀ ni wá.

15. Bí ó ṣe ti ènìyàn ni, ọjọ́ Rẹ̀ dà bí koríko,ó gbilẹ̀ bí ìtànnà ewéko ìgbẹ́;

16. Afẹ́fẹ́ fẹ́ kọjá lọ lórí Rẹ̀,kò sì rántí ibùjókòó Rẹ̀ mọ́.

Ka pipe ipin Sáàmù 103