Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Sáàmù 103:1-14 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

1. Yin Olúwa, ìwọ ọkàn mi; àti gbogbo ohun tí ó wà nínú mi, yín orúkọ Rẹ̀ mímọ́.

2. Yin Olúwa, ìwọ ọkàn mi, kí o má ṣe gbàgbé gbogbo oore Rẹ̀

3. Ẹni tí ó dárí gbogbo ẹ̀ṣẹ̀ Rẹ̀ jìn ọ́ tíó sì wo gbogbo àrùn Rẹ̀ sàn,

4. Ẹni tí o ra ẹ̀mí Rẹ padà kúrò nínú kòtò ikúẹni tí o fi ìṣeun ìfẹ́ àti ìyọ́nú dé ọ ní adé,

5. Ẹni tí o fi ohun dídara tẹ́ ọ lọ́rùnkí ìgbà èwe Rẹ̀ le di ọ̀tún bí ti ẹyẹ idì.

6. Olúwa ń ṣe òdodo àti ìdájọ́ fúngbogbo àwọn tí a nilára.

7. Ó fi ọ̀nà Rẹ̀ hàn fún Mósè, iṣẹ́ Rẹ̀ fun àwọn ọmọ Ísírẹ́lì;

8. Olúwa ni aláàánú àti olóore,ó lọ́ra láti bínú, ó sì pọ̀ ní ìfẹ́.

9. Òun kì í bá ni wí ní ìgbà gbogbobẹ́ẹ̀ ni kì í pa ìbínú Rẹ mọ́ láéláé;

10. Òun kì í ṣe sí wá gẹ́gẹ́ bí ẹ̀ṣẹ̀ wabẹ́ẹ̀ ni kì í san-án fún wa gẹ́gẹ́bí àìṣedédé wa.

11. Nítorí bí ọ̀run ṣe ga sílẹ̀,bẹ́ẹ̀ ni ìfẹ́ Rẹ̀ tóbi sí àwọn tí ó bẹ̀rù Rẹ̀.

12. Bí ìlà òòrùn ti jìnnà sí ìwọ̀ òòrunbẹ́ẹ̀ ní ó ṣe mú ìrékọjá wá jìnnà sí wa.

13. Bí bàbá ti ń ṣe ìyọ́nú sí àwọn ọmọ Rẹ̀,bẹ́ẹ̀ ni Olúwa ń ṣe ìyọ́nú sí àwọn tí ó bẹ̀rù Rẹ̀;

14. Nítorí tí ó mọ dídá wa,ó rántí pé erùpẹ̀ ni wá.

Ka pipe ipin Sáàmù 103