Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Sáàmù 102:21-28 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

21. Kí a lè sọ orúkọ Olúwa ni Síónìàti ìyìn Rẹ̀ ní Jérúsálẹ́mù.

22. Ní ìgbà tí a kó àwọn ènìyàn àtiìjọba pọ̀ láti máa sìn Olúwa.

23. Ní ipa ọ̀nà mi, ó Rẹ agbára mi sílẹ̀,ó gé ọjọ́ mi kúrú.

24. Èmi sì wí pé;“Ọlọ́run mi, Má ṣe mú mi kúrò ní agbede-méjì ọjọ́ mi; ọdún Rẹ̀ ń lọ láti ìran dé ìran.

25. Ní ìbẹ̀rẹ̀ ní ìwọ fi ìpilẹ̀ ayé sọlẹ̀,ọrun si jẹ́ iṣẹ́ ọwọ́ Rẹ.

26. Wọn yóò ṣègbé, wọn yóò parun, ṣùgbọ́n ìwọ yóò wà;gbogbo wọn ni yóò gbó bí aṣọ.Bí ẹ̀wù ni ìwọ yóò pààrọ̀ wọnwọn yóò sì di àpatì.

27. Ṣùgbọ́n ìwọ wà digbí ṣíbẹ̀,ọdún Rẹ kò sì ni òpin.

28. Àwọn ọmọ ìránṣẹ́ Rẹ̀ yóò dúró ní iwájú Rẹ pẹ́;a o sì fi ẹsẹ̀ irú ọmọ wọn sọlẹ̀ ní iwájú Rẹ.”

Ka pipe ipin Sáàmù 102