Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Sáàmù 102:16-21 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

16. Torí tí Olúwa yóò gbé Síónì ró, yóò farahàn nínú ògo Rẹ̀.

17. Yóò dáhùn àdúrà àwọn aláìní;kì yóò si gan ẹ̀bẹ̀ wọn.

18. Jẹ́ kí a kọ èyí fún ìran tí ń bọ̀,àwọn ènìyàn tí a kò tí ì dá yóò yin Olúwa:

19. “Olúwa wo ilẹ̀ láti òkè mímọ́ Rẹ̀ wáláti ọ̀run wá ni ó bojúwo ayé,

20. Láti gbọ́ ìrora ará túbú, lati túàwọn tí a yàn sí ikú sílẹ̀.”

21. Kí a lè sọ orúkọ Olúwa ni Síónìàti ìyìn Rẹ̀ ní Jérúsálẹ́mù.

Ka pipe ipin Sáàmù 102