1. Gbọ́ àdúrà mi, Olúwa:Jẹ́ kí igbe ẹ̀bẹ̀ mi kí ó wá sí ọ̀dọ̀ Rẹ
2. Má ṣe pa ojú Rẹ mọ́ kúrò lọ́dọ̀ miní ọjọ́ tí èmi wà nínú ìpọ́njú.Dẹ etí Rẹ sí mi;nígbà tí mo bá pè, dámi lóhùn kíákíá.
3. Nítorí tí ọjọ́ rú bí èéfin;egungun mi sì jóná bí ààrò
4. Àyà mi lù, ó sì rọ bí i koríko;mo gbàgbé láti jẹ oúnjẹ mi.
5. Nítorí ohùn ìkérora mi,egungun mi lẹ̀ mọ́ ẹran ara mi.
6. Èmi dà bí ẹyẹ igún ni ijù:èmi dàbí òwìwí ibi ahoro.
7. Èmi dìde; èmí dàbí ẹyẹ lórí ilé.
8. Ní ọjọ́ gbogbo àwọn ọ̀ta ológosẹ́ mi ń gàn mí;àwọn tí ń ṣe ìkanra sí mi ń fi orúkọ mi bú.
9. Èmi jẹ eérú gẹ́gẹ́ bí oúnjẹ mi, èmi si da ohun mímu mi pọ̀ pẹ̀lú omíjé.