Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Sáàmù 102:1-16 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

1. Gbọ́ àdúrà mi, Olúwa:Jẹ́ kí igbe ẹ̀bẹ̀ mi kí ó wá sí ọ̀dọ̀ Rẹ

2. Má ṣe pa ojú Rẹ mọ́ kúrò lọ́dọ̀ miní ọjọ́ tí èmi wà nínú ìpọ́njú.Dẹ etí Rẹ sí mi;nígbà tí mo bá pè, dámi lóhùn kíákíá.

3. Nítorí tí ọjọ́ rú bí èéfin;egungun mi sì jóná bí ààrò

4. Àyà mi lù, ó sì rọ bí i koríko;mo gbàgbé láti jẹ oúnjẹ mi.

5. Nítorí ohùn ìkérora mi,egungun mi lẹ̀ mọ́ ẹran ara mi.

6. Èmi dà bí ẹyẹ igún ni ijù:èmi dàbí òwìwí ibi ahoro.

7. Èmi dìde; èmí dàbí ẹyẹ lórí ilé.

8. Ní ọjọ́ gbogbo àwọn ọ̀ta ológosẹ́ mi ń gàn mí;àwọn tí ń ṣe ìkanra sí mi ń fi orúkọ mi bú.

9. Èmi jẹ eérú gẹ́gẹ́ bí oúnjẹ mi, èmi si da ohun mímu mi pọ̀ pẹ̀lú omíjé.

10. Nítorí ìbínú ríru Rẹ, nítorí ìwọ ti gbé mi sókè, ìwọ sì gbé mi ṣánlẹ̀.

11. Ọjọ́ mi dàbí òjìji àṣálẹ́èmi sì rọ bí koríko

12. Ṣùgbọ́n ìwọ, Olúwa, ni yóò dúró láéláé;ìrántí Rẹ láti ìran dé ìran.

13. Ìwọ ó dìde ìwọ o sì ṣàánú fún Síónì,nítorí ìgbà àti ṣe ojú rere sí i;àkókò náà ti dé.

14. Nítorí tí àwọn òkúta jẹ́ inú dídùnsí àwọn ìránṣẹ́ Rẹ; wọ́n sì káànú ẹrùpẹ̀ Rẹ.

15. Àwọn ayé yóò bẹ̀rù orúkọ Olúwa,gbogbo ọba ayé yóò máa bẹ̀rù ògo Rẹ.

16. Torí tí Olúwa yóò gbé Síónì ró, yóò farahàn nínú ògo Rẹ̀.

Ka pipe ipin Sáàmù 102