Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Sáàmù 10:7-18 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

7. Ẹnu Rẹ̀ kún fún ẹ̀gàn àti irọ́ àti ìtànjẹ;wàhálà àti ohun búburú wa lábẹ́ ahọ́n Rẹ̀.

8. Ó lúgọ ní bùba nítòsí ìletò;ó gọ níbi ìkọ̀kọ̀ láti pa aláìṣẹ̀,ojú Rẹ̀ ń ṣọ́ àwọn talákà ní ìkọ̀kọ̀.

9. O lúgọ ní bùba nínú pàǹtí;ó lúgọ ní bùba làti mú àwọn aláìní ìrànwọ́;ó mú àwọn aláìlólùrànlọ́wọ́, ó sì wọ́ wọn lọ sínú àwọ̀n Rẹ̀.

10. Àwọn ẹni ìpalára Rẹ̀ run, ó Rẹ ara Rẹ̀ sílẹ̀;kí talákà bá a le bọ́ sí ọwọ́ agbára Rẹ̀.

11. Ó wí fún ara Rẹ̀, “Ọlọ́run ti gbàgbé;Ó pa ojú Rẹ̀ mọ́ òun kì yóò rí i láéláé.”

12. Dìde, Olúwa! Gbé ọwọ́ Rẹ̀ sókè, Ọlọ́run.Má ṣe gbàgbé àwọn olùpọ́njú.

13. Èeṣe tí ènìyàn búburú ṣe ń kẹ́gàn Ọlọ́run?Èéṣe tí o fi wí nínú ọkàn ara Rẹ̀,“Kò ní pé mí láti ṣe ìṣirò”?

14. Ṣùgbọ́n ìwọ, Ọlọ́run, ni o ri wàhálà àti ìrora;Ìwọ rò láti fi sí ọwọ́ Rẹ.talákà fara Rẹ̀ jin fún ọ;Ìwọ ni olùrànlọ́wọ́ àwọn aláìní baba.

15. Ṣẹ́ apá àwọn ènìyàn búburú àti ènìyàn ibi;pèé láti wa sírò fún iwà ìkà Rẹ̀tí a kò le è rí.

16. Olúwa ń jọba láé àti láéláé;àwọn orílẹ̀ èdè yóò ti ilẹ̀ Rẹ̀ ṣègbé.

17. Ìwọ́ gbọ, Olúwa, ìfẹ́ àwọn tí a ni lára;Ìwọ gbà wọ́n níyànjú, ó sì gbọ́ ìgbe wọn,

18. Láti ṣe ìdájọ́ àwọn aláìni baba àti àwọn ti a ni lára,kí ọkùnrin, tí ó wà ní àyé, kí ó má ṣe dẹ́rùbà ni mọ́.

Ka pipe ipin Sáàmù 10