Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Sáàmù 10:2-15 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

2. Nínú àrékérekè ènìyàn búburú ti ó gbérò ni kí a ti mú wọn,lí a mú-un nínú ìlànà tí o gbérò.

3. Ó ń fọ́nnu nínú ìfẹ́ inú ọkàn Rẹ̀;o bùkún olójúkòkòrò ó sì ń kẹ́gàn Olúwa

4. Ènìyàn búburú kò lè rí i nínú ìgbéraga Rẹ̀;kò sí àyè fún Ọlọ́run nínú gbogbo èrò Rẹ̀;

5. Ọ̀nà Rẹ̀ ń gún régé nígbà gbogbo;òun ń gbéraga, òfin Rẹ sì jìnnà sí i;òun kẹ́gàn àwọn ọ̀ta Rẹ̀.

6. O wí fún ara Rẹ̀, “Kò si ohun tí ó le mì mí;Inú mi yóò máa dùn nígbà gbogbo èmi kò si ní ní wàhálà.”

7. Ẹnu Rẹ̀ kún fún ẹ̀gàn àti irọ́ àti ìtànjẹ;wàhálà àti ohun búburú wa lábẹ́ ahọ́n Rẹ̀.

8. Ó lúgọ ní bùba nítòsí ìletò;ó gọ níbi ìkọ̀kọ̀ láti pa aláìṣẹ̀,ojú Rẹ̀ ń ṣọ́ àwọn talákà ní ìkọ̀kọ̀.

9. O lúgọ ní bùba nínú pàǹtí;ó lúgọ ní bùba làti mú àwọn aláìní ìrànwọ́;ó mú àwọn aláìlólùrànlọ́wọ́, ó sì wọ́ wọn lọ sínú àwọ̀n Rẹ̀.

10. Àwọn ẹni ìpalára Rẹ̀ run, ó Rẹ ara Rẹ̀ sílẹ̀;kí talákà bá a le bọ́ sí ọwọ́ agbára Rẹ̀.

11. Ó wí fún ara Rẹ̀, “Ọlọ́run ti gbàgbé;Ó pa ojú Rẹ̀ mọ́ òun kì yóò rí i láéláé.”

12. Dìde, Olúwa! Gbé ọwọ́ Rẹ̀ sókè, Ọlọ́run.Má ṣe gbàgbé àwọn olùpọ́njú.

13. Èeṣe tí ènìyàn búburú ṣe ń kẹ́gàn Ọlọ́run?Èéṣe tí o fi wí nínú ọkàn ara Rẹ̀,“Kò ní pé mí láti ṣe ìṣirò”?

14. Ṣùgbọ́n ìwọ, Ọlọ́run, ni o ri wàhálà àti ìrora;Ìwọ rò láti fi sí ọwọ́ Rẹ.talákà fara Rẹ̀ jin fún ọ;Ìwọ ni olùrànlọ́wọ́ àwọn aláìní baba.

15. Ṣẹ́ apá àwọn ènìyàn búburú àti ènìyàn ibi;pèé láti wa sírò fún iwà ìkà Rẹ̀tí a kò le è rí.

Ka pipe ipin Sáàmù 10