Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Rúùtù 4:14-22 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

14. Àwọn obìnrin sì wí fún Náómì pé, “Ìyìn ni fún Olúwa tí kò fi ọ sílẹ̀ ní òní yìí láìní ìbátan, Olùràpadà. Kí ọmọ náà di olókìkí ní Ísírẹ́lì.

15. Yóò tún ayé rẹ ṣe, yóò sì dáàbò bò ọ́ ní ọjọ́ ogbó rẹ. Nítorí pé ìyàwó ọmọ rẹ, èyí tí ó sàn fún ọ ju ọmọkùnrin méje lọ, tí ó sì fẹ́ràn rẹ ni ó bí ọmọ yìí fún.”

16. Náómì sì gbé ọmọ náà lé orí ẹsẹ̀ rẹ̀, ó sì ń tọ́jú rẹ̀.

17. Àwọn obìnrin àdúgbò sì wí pé, “A bí ọmọkùnrin kan fún Náómì.” Wọ́n sì pe orúkọ rẹ̀ ní Óbédì. Òun sì ni baba Jésè tí í ṣe baba Dáfídì.

18. Èyí ni ìran Pérésì:Pérésì ni baba Ésírónì,

19. Ésírónì ni baba Rámú,Rámù ni baba Ámínádábù

20. Ámínádábù ni baba Násónì,Násónì ni baba Sálímónì,

21. Sálímónì ni baba Bóásì,Bóásì ni baba Óbédì,

22. Óbédì ní baba Jésè,Jésè ni baba Dáfídì.

Ka pipe ipin Rúùtù 4