Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Rúùtù 4:1-6 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

1. Nígbà náà ni Bóásì gòkè lọ sí ẹnu ìbodè ìlú, ó sì jòkòó síbẹ̀. Nígbà tí ìbátan tí ó sún mọ́ Elimélékì jùlọ, arákùnrin tí Bóásì ti sọ̀rọ̀ rẹ̀ ń kọjá, Bóásì pè é wí pé, “Máa bọ̀ wá síbí ìwọ ọ̀rẹ́ mi, kí o sì jokòó.” Ó sì lọ jokòó.

2. Bóásì sì pe mẹ́wàá nínú àwọn àgbààgbà ìlú, wí pé ki wọn jókòó, wọn sí se bẹ́ẹ̀,

3. ó sì sọ fún ìbátan rẹ̀ náà pé, “Arábìnrin Náómì tí ó dé láti ilẹ̀ Móábù fẹ́ ta ilẹ̀, èyí tí ó ṣe ti arákùnrin wa, Elimélékì.

4. Mó sì rò wí pé ó yẹ kí n mú ọ̀rọ̀ náà wá sí etí ìgbọ́ rẹ, wí pé kí o rà á ní iwájú gbogbo àwọn tí ó jòkòó sí ibi yìí. Bí ìwọ yóò bá rà á padà, rà á. Ṣùgbọ́n bí ìwọ kò bá ní rà á padà, sọ fún mi, kí èmi ó le è mọ̀. Nítorí pé kò sí ẹlòmíràn tí ó ní ẹ̀tọ́ láti rà á ju ìwọ lọ, èmi sì ni ẹni tí ó tún kàn lẹ́yìn rẹ̀.”Ọkùnrin náà sì sọ wí pé, “Èmi yóò rà á padà.”

5. Nígbà náà ni, Bóásì sọ wí pé, “Bí ìwọ bá ti ra ilẹ̀ náà lọ́wọ́ Náómì àti lọ́wọ́ Rúùtù ará Móábù, ìwọ gbọdọ̀ fẹ opó ọkùnrin náà, kí orúkọ ọkùnrin tí ó kú náà má ba à parẹ́ pẹ̀lú ohun ìní rẹ̀ àti kí o le è bímọ ní orúkọ rẹ̀.”

6. Nígbà náà ni ọkùnrin náà dáhùn sí èyí pé, “Nípa ti èyí, èmi kò le rà á padà, nítorí pé, ọmọ rẹ, ọkùnrin yóò wá jẹ́ ajogún àwọn ohun-ìní mi pẹ̀lú. Rà á fún ara rẹ, èmi kò le ṣe é.”

Ka pipe ipin Rúùtù 4