Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Òwe 9:7-13 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

7. “Ẹnikẹ́ni tí ó bá bá ẹlẹ́gàn wí, kọ lẹ́tà sí àbùkùẹnikẹ́ni tí ó bá bá ẹni búburú wí kọ lẹ́tà sí èébú.

8. Má ṣe bá ẹlẹ́gàn wí, àìṣebẹ́ẹ̀ yóò kórìíra rẹ.Bá Ọlọgbọ́n wí yóò sì fẹ́ràn rẹ;

9. kọ́ Ọlọgbọ́n ènìyàn lẹ́kọ̀ọ́, yóò sì gbọ́n sí ikọ́ Olódodo ènìyàn lẹ́kọ̀ọ́, yóò sì fi kún ìmọ̀ rẹ̀.

10. “Ìbẹ̀rù Olúwa ni ìbẹ̀rẹ̀ ọgbọ́n,ìmọ̀ nípa Ẹni mímọ́ ni òye.

11. Nítorí nípasẹ̀ mi ọjọ́ rẹ yóò gùnọ̀pọ̀lọpọ̀ ọdún yóò sì kún ọjọ́ ayé rẹ.

12. Bí ìwọ bá gbọ́n, ọgbọ́n rẹ yóò fún ọ ní èrè:bí ìwọ bá jẹ́ ẹlẹ́gàn, ìwọ nìkan ni yóò jìyà.”

13. Òmùgọ̀ obìnrin jẹ́ aláriwo;ó jẹ́ aláìlẹ́kọ̀ọ́ àti aláì ní ìmọ̀.

Ka pipe ipin Òwe 9