1. Ọgbọ́n ti kọ́ ilé rẹ̀,ó ti gbẹ́ òpó o rẹ̀ méjèèjì
2. ó ti fi ilé pọn tí ó ti fọ̀nà rokàó sì ti ṣètò o tábìlì oúnjẹ rẹ̀
3. ó ti rán àwọn ìránṣẹ́bìnrin rẹ̀ jáde, ó sì ń pè,láti ibi tí ó ga jù láàrin ìlú.
4. “Jẹ́ kí gbogbo àwọn aláìgbọ́n wọ ibí wá!”Ó ń wí fún àwọn tí kò lọ́gbọ́n pé
5. “Wá, ẹ wá fẹ́ oúnjẹ misì mu wáìnì tí mo ti pò pọ̀.
6. Fi ìwà àìmọ̀kan rẹ sílẹ̀ ìwọ yóò sì yè;rìn ní ọ̀nà òye.
7. “Ẹnikẹ́ni tí ó bá bá ẹlẹ́gàn wí, kọ lẹ́tà sí àbùkùẹnikẹ́ni tí ó bá bá ẹni búburú wí kọ lẹ́tà sí èébú.
8. Má ṣe bá ẹlẹ́gàn wí, àìṣebẹ́ẹ̀ yóò kórìíra rẹ.Bá Ọlọgbọ́n wí yóò sì fẹ́ràn rẹ;
9. kọ́ Ọlọgbọ́n ènìyàn lẹ́kọ̀ọ́, yóò sì gbọ́n sí ikọ́ Olódodo ènìyàn lẹ́kọ̀ọ́, yóò sì fi kún ìmọ̀ rẹ̀.