Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Òwe 6:9-21 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

9. Yóò ti pẹ́ tó tí ìwọ yóò dùbúlẹ̀, ìwọ ọ̀lẹ?Nígbà wo ni ìwọ yóò jí kúrò lójú oorun rẹ?

10. Oorun díẹ̀, Òògbé díẹ̀,ìkáwọ́gbera láti sinmi díẹ̀

11. Òsì yóò sì wá sórí rẹ bí ìgárá ọlọ́ṣààti àìní bí adigunjalè.

12. Ènìyàn kénìyàn àti ènìyàn búburú,tí ń ru ẹnu àrékérekè káàkiri,

13. tí ó ń sẹ́jú pàkòpàkò,ó ń fi ẹsẹ̀ ṣe àmìó sì ń fi ìka ọwọ́ rẹ̀ júwe,

14. tí ó ń pète búburú pẹ̀lú ẹ̀tàn nínú ọkàn rẹ̀ìgbà gbogbo ni ó máa ń dá ìjà sílẹ̀.

15. Nítorí náà ìdààmú yóò dé báa ní ìsẹ́jú akàn;yóò parun lójijì láì sí àtúnṣe.

16. Àwọn ohun mẹ́fà wà tí Olúwa kórìíra,ohun méje ní ó jẹ́ ìríra síi:

17. Ojú ìgbéraga,Ahọ́n tó ń parọ́ọwọ́ tí ń ta ẹ̀jẹ̀ aláìṣẹ̀ sílẹ̀,

18. ọkàn tí ń pète ohun búburú,ẹsẹ̀ tí ó yára láti sáré sínú ìwà ìkà,

19. Ajẹ́rìí èké tí ń tú irọ́ jáde lẹ́nuàti ènìyàn tí ń dá ìjà sílẹ̀ láàrin àwọn ọmọ ìyá kan.

20. Ọmọ mi, pa àṣẹ baba rẹ mọ́má sì ṣe kọ ẹ̀kọ́ ìyá rẹ sílẹ̀.

21. Jẹ́ kí wọn wà nínú ọkàn rẹ láéláéso wọ́n mọ́ ọrùn rẹ

Ka pipe ipin Òwe 6