Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Òwe 6:24-35 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

24. yóò pa ọ́ mọ́ kúrò lọ́dọ̀ obìnrin oníṣekúṣekúrò lọ́wọ́ ẹnu dídùn aya tí ń rin ìrìnkurìn

25. Má ṣe ṣe ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ síi nínú ọkàn rẹ nítorí ẹwà rẹtàbí kí o jẹ́ kí ó fi ojú rẹ̀ fà ọ́ mọ́ra,

26. nítorí Aṣẹ́wó yóò sọ ọ́ di àkàrà lásánlàsànẹ̀mí rẹ gan an sì ni alágbérè ń dọdẹ.

27. Ǹjẹ́ ènìyàn ha le è gbé iná lé orí itankí aṣọ rẹ̀ sì má jòó?

28. Ǹjẹ́ ènìyàn le è máa rìn lórí iná?Kí ẹṣẹ̀ rẹ̀ sì má jóná?

29. Bẹ́ẹ̀ ni ẹni tí ń lọ sùn pẹ̀lú aya aláya;kò sí ẹni tí ó fọwọ́ kàn án tí yóò lọ láì jìyà.

30. Àwọn ènìyàn kì í kẹ́gàn olè tí ó bá jalènítorí àti jẹun nígbà tí ebi bá ń pa á.

31. Ṣíbẹ̀ bí ọwọ́ bá tẹ̀ẹ́, ó gbọdọ̀ san ìlọ́po méjebí ó tilẹ̀ kó gbogbo ohun tó ní nílé tà.

32. Ṣùgbọ́n ẹni tí ń ṣe àgbérè kò nírònú;ẹnikẹ́ni tí ó bá ń ṣe bẹ́ẹ̀ ó ń pa ara rẹ̀ run ni

33. Ìfarapa àti ìtìjú ni tirẹ̀,ẹ̀gàn rẹ̀ kì yóò sì kúrò láéláé;

34. nítorí owú yóò ru ìbínú ọkọ sókè,kì yóò sì ṣàánú nígbà tí ó bá ń gbẹ̀san.

35. Kò ní gba nǹkankan bí ohun ìtanràn;yóò kọ àbẹ̀tẹ́lẹ̀, bí ó ti wù kí ó pọ̀ tó.

Ka pipe ipin Òwe 6