Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Òwe 6:2-12 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

2. Bí a bá ti fi ọ̀rọ̀ tí ó sọ dẹkùn mú ọ,tí ọ̀rọ̀ ẹnu rẹ ti kó ọ sí pàkúté,

3. Nígbà náà, ṣe èyí, ìwọ ọmọ mi, láti gba ara rẹníwọ̀n bí o ti kó sọ́wọ́ aládùúgbò rẹ:lọ kí o sì rẹ ara rẹ sílẹ̀;bẹ aládùúgbò rẹ dáadáa

4. Má ṣe jẹ́ kí oorun kí ó kùn ọ́,tàbí kí o tilẹ̀ tòògbé rárá.

5. Gba ara rẹ sílẹ̀, bí abo àgbọ̀nrín kúrò lọ́wọ́ ọdẹ,bí ẹyẹ kúrò nínú okùn àwọn pẹyẹpẹyẹ.

6. Tọ èèrùn lọ, ìwọ ọ̀lẹkíyèsí ìṣe rẹ̀, kí o sì gbọ́n!

7. Kò ní olùdarí,kò sí alábojútó tàbí ọba,

8. síbẹ̀, a kó ìpèsè rẹ̀ jọ ní àsìkò òjòyóò sì kó oúnjẹ rẹ̀ jọ ní àsìkò ìkórè.

9. Yóò ti pẹ́ tó tí ìwọ yóò dùbúlẹ̀, ìwọ ọ̀lẹ?Nígbà wo ni ìwọ yóò jí kúrò lójú oorun rẹ?

10. Oorun díẹ̀, Òògbé díẹ̀,ìkáwọ́gbera láti sinmi díẹ̀

11. Òsì yóò sì wá sórí rẹ bí ìgárá ọlọ́ṣààti àìní bí adigunjalè.

12. Ènìyàn kénìyàn àti ènìyàn búburú,tí ń ru ẹnu àrékérekè káàkiri,

Ka pipe ipin Òwe 6