Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Òwe 6:15-19 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

15. Nítorí náà ìdààmú yóò dé báa ní ìsẹ́jú akàn;yóò parun lójijì láì sí àtúnṣe.

16. Àwọn ohun mẹ́fà wà tí Olúwa kórìíra,ohun méje ní ó jẹ́ ìríra síi:

17. Ojú ìgbéraga,Ahọ́n tó ń parọ́ọwọ́ tí ń ta ẹ̀jẹ̀ aláìṣẹ̀ sílẹ̀,

18. ọkàn tí ń pète ohun búburú,ẹsẹ̀ tí ó yára láti sáré sínú ìwà ìkà,

19. Ajẹ́rìí èké tí ń tú irọ́ jáde lẹ́nuàti ènìyàn tí ń dá ìjà sílẹ̀ láàrin àwọn ọmọ ìyá kan.

Ka pipe ipin Òwe 6