Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Òwe 6:1-7 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

1. Ọmọ mi, bí ìwọ bá ṣe oníduúró fún aládùúgbò rẹbí ìwọ bá ti bọwọ́ ní ìlérí májẹ̀mu pẹ̀lú ẹlòmíràn

2. Bí a bá ti fi ọ̀rọ̀ tí ó sọ dẹkùn mú ọ,tí ọ̀rọ̀ ẹnu rẹ ti kó ọ sí pàkúté,

3. Nígbà náà, ṣe èyí, ìwọ ọmọ mi, láti gba ara rẹníwọ̀n bí o ti kó sọ́wọ́ aládùúgbò rẹ:lọ kí o sì rẹ ara rẹ sílẹ̀;bẹ aládùúgbò rẹ dáadáa

4. Má ṣe jẹ́ kí oorun kí ó kùn ọ́,tàbí kí o tilẹ̀ tòògbé rárá.

5. Gba ara rẹ sílẹ̀, bí abo àgbọ̀nrín kúrò lọ́wọ́ ọdẹ,bí ẹyẹ kúrò nínú okùn àwọn pẹyẹpẹyẹ.

6. Tọ èèrùn lọ, ìwọ ọ̀lẹkíyèsí ìṣe rẹ̀, kí o sì gbọ́n!

7. Kò ní olùdarí,kò sí alábojútó tàbí ọba,

Ka pipe ipin Òwe 6