Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Òwe 5:19-23 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

19. Abo àgbọ̀nrín tó dára, ìgalà tí ó wu ni jọjọJẹ́ kí ọmú rẹ̀ tẹ́ ọ lọ́rùn nígbà gbogbojẹ́ kí ìfẹ́ rẹ̀ máa fà ọ́ títí láéláé

20. Ọmọ mi, èéṣe tí ìfẹ́ aṣẹ́wó fi ń fà ọ́tí ìwọ sì ń dì mọ́ ìyàwó ẹlòmíràn?

21. Nítorí ọ̀nà ènìyàn kò farasin rárá fún OlúwaÓ sì ń gbé gbogbo ọ̀nà rẹ̀ yẹ̀wò

22. Ìwà búburú ènìyàn búburú ni yóò mú kó bọ́ sínú okùn;okùn ẹ̀ṣẹ̀ ẹ rẹ̀ dì í le kankan

23. Yóò kú nítorí àìgba ẹ̀kọ́ìwà òmùgọ̀ ara rẹ̀ ló mú kó ṣáko lọ.

Ka pipe ipin Òwe 5