Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Òwe 5:10-18 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

10. kí àwọn àjòjì ó má baà fi ọrọ̀ rẹ ṣara rindinkí làálàá rẹ sì sọ ilé ẹlòmíràn di ọlọ́rọ̀.

11. Ní ìgbẹ̀yìn ayé rẹ ìwọ yóò kérora,nígbà tí agbára rẹ àti ara rẹ bá ti joro tán

12. Ìwọ yóò wí pé, “Mo ti kórìíra ẹ̀kọ́ tó!Ọkàn mi ṣe wá kóòríra ìbáwí!

13. N kò gbọ́ràn sí àwọn olùkọ́ mi lẹ́nu,tàbí kí n fetí sí àwọn tí ń kọ́ mi lẹ́kọ̀ọ́.

14. Mo ti bẹ̀rẹ̀ ìparun pátapátaní àárin gbogbo àwùjọ ènìyàn.”

15. Mu omi láti inú un kànga tìrẹOmi tí ń ṣàn láti inú kànga rẹ.

16. Ó ha yẹ kí omi ìṣun rẹ kún àkúnya sí ojú ọ̀nààti odò tí ń sàn lọ sí àárin ọjà?

17. Jẹ́ kí wọn jẹ́ tìrẹ nìkan,má ṣe ṣe àjọpín wọn pẹ̀lú àjòjì láéláé.

18. Ǹjẹ́, kí oríṣun rẹ di àbùkù fún;kí ó sì yọ nínú aya ìgbà èwe rẹ.

Ka pipe ipin Òwe 5