Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Òwe 5:1-9 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

1. Ọmọ mi, fiyè sí ọgbọ́n ọ̀n mi tẹ́tí sílẹ̀ dáradára sí ọ̀rọ̀ àròjinlẹ̀mi

2. kí ìwọ sì lè ní ìṣọ́rakí ètè rẹ sì le pa ìmọ̀ mọ́.

3. Nítorí ètè alágbèrè aṣẹ́wó obìnrin a máa ṣun oyin,ọ̀rọ̀ rẹ̀ sì kúnná ju òróró lọ

4. ṣùgbọ́n ní ìgbẹ̀yìngbẹ́yín, ó korò ju òróòro lọó mú bí idà olójú méjì.

5. Ẹsẹ̀ rẹ̀ lọ sí ọ̀nà ikúìgbéṣẹ̀ rẹ̀ lọ tààrà sí ibojì òkú.

6. Kò tilẹ̀ ronú nípa ọ̀nà ìyèọ̀nà rẹ̀ rí pálapàla, ṣùgbọ́n kò tilẹ̀ mọ́.

7. Nítorí náà, ẹ̀yin ọmọ tẹ́tí sí mimá ṣe yàgò kúrò nínú àwọn nǹkan tí mo sọ

8. Rìn ní ọ̀nà tí ó jìnnà síi dáadáamá ṣe súnmọ́ ẹnu ọ̀nà ilé rẹ̀

9. àìṣe bẹ́ẹ̀ ìwọ yóò gbé gbogbo agbára rẹ lé ẹlòmíràn lọ́wọ́àti ọjọ́ ayé rẹ fún ìkà ènìyàn

Ka pipe ipin Òwe 5