Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Òwe 31:8-23 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

8. “Ṣọ̀rọ̀ lórúkọ àwọn tí kò le sọ̀rọ̀ fún ra wọnfún ẹ̀tọ́ àwọn ẹni tí ń parun

9. sọ̀rọ̀ kí o sì ṣe ìdájọ́ àìṣègbèjà fún ẹ̀tọ́ àwọn tálákà àti aláìní.”

10. Ta ni ó le rí aya oníwà rere?Ó níye lórí ju iyùn lọ

11. ọkọ rẹ̀ ní ìgbẹ́kẹ̀lẹ́ púpọ̀ nínú rẹ̀kò sì sí ìwà rere tí kò pé lọ́wọ́ rẹ̀.

12. Ire ní ó ń ṣe fún un, kì í ṣe ibiní gbogbo ọjọ́ ayé rẹ̀.

13. Ó sa aṣọ irun àgùtàn olówùú àti ọ̀gbọ̀Ó sì ṣiṣẹ́ pẹ̀lú ìyárí.

14. Ó dàbí ọkọ̀ ojú omi tí àwọn oníṣòwò;ó ń gbé oúnjẹ rẹ̀ wá láti ọ̀nà jínjìn

15. Ó dìde nígbà tí òkùnkùn sì kùn;ó ṣe oúnjẹ fún ìdílé rẹ̀àti ìpín oúnjẹ fún àwọn ìránṣẹ́-bìnrin rẹ̀.

16. Ó kíyèsí oko kan, ó sì rà á;nínú ohun tí ó ń wọlé fún un ó gbin àjàrà rẹ̀

17. Ó bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ rẹ̀ tagbáratagbáraApá rẹ̀ le koko fún iṣẹ́

18. Ó ríi pé òwò òun péfìtílà rẹ̀ kì í sìí kú ní òru

19. Ní ọwọ́ rẹ̀, ó di kẹ̀kẹ́ òwú múó sì na ọwọ́ rẹ̀ di ìrànwú mú

20. ó la ọwọ́ rẹ̀ sí àwọn talákàó sì na ọwọ́ rẹ̀ sí àwọn aláìní.

21. Nígbà tí òjò dídì rọ̀, kò bẹ̀rù nítorí ìdílé rẹ̀nítorí gbogbo wọn ni ó wọ aṣọ tí ó nípọn.

22. Ó ṣe aṣọ títẹ́ fún ibùsùn rẹ̀;ẹwu dáradára àti eléṣè é àlùkò ni aṣọ rẹ̀

23. A bọ̀wọ̀ fún ọkọ rẹ̀ ní ẹnu ibòde ìlúníbi tí ó ń jókòó láàrin àwọn àgbà ìlú

Ka pipe ipin Òwe 31