Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Òwe 31:7-22 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

7. Jẹ́ kí wọn mu ọtí kí wọn sì gbàgbé òsì wọnkí wọn má sì rántí òsì wọn mọ́.

8. “Ṣọ̀rọ̀ lórúkọ àwọn tí kò le sọ̀rọ̀ fún ra wọnfún ẹ̀tọ́ àwọn ẹni tí ń parun

9. sọ̀rọ̀ kí o sì ṣe ìdájọ́ àìṣègbèjà fún ẹ̀tọ́ àwọn tálákà àti aláìní.”

10. Ta ni ó le rí aya oníwà rere?Ó níye lórí ju iyùn lọ

11. ọkọ rẹ̀ ní ìgbẹ́kẹ̀lẹ́ púpọ̀ nínú rẹ̀kò sì sí ìwà rere tí kò pé lọ́wọ́ rẹ̀.

12. Ire ní ó ń ṣe fún un, kì í ṣe ibiní gbogbo ọjọ́ ayé rẹ̀.

13. Ó sa aṣọ irun àgùtàn olówùú àti ọ̀gbọ̀Ó sì ṣiṣẹ́ pẹ̀lú ìyárí.

14. Ó dàbí ọkọ̀ ojú omi tí àwọn oníṣòwò;ó ń gbé oúnjẹ rẹ̀ wá láti ọ̀nà jínjìn

15. Ó dìde nígbà tí òkùnkùn sì kùn;ó ṣe oúnjẹ fún ìdílé rẹ̀àti ìpín oúnjẹ fún àwọn ìránṣẹ́-bìnrin rẹ̀.

16. Ó kíyèsí oko kan, ó sì rà á;nínú ohun tí ó ń wọlé fún un ó gbin àjàrà rẹ̀

17. Ó bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ rẹ̀ tagbáratagbáraApá rẹ̀ le koko fún iṣẹ́

18. Ó ríi pé òwò òun péfìtílà rẹ̀ kì í sìí kú ní òru

19. Ní ọwọ́ rẹ̀, ó di kẹ̀kẹ́ òwú múó sì na ọwọ́ rẹ̀ di ìrànwú mú

20. ó la ọwọ́ rẹ̀ sí àwọn talákàó sì na ọwọ́ rẹ̀ sí àwọn aláìní.

21. Nígbà tí òjò dídì rọ̀, kò bẹ̀rù nítorí ìdílé rẹ̀nítorí gbogbo wọn ni ó wọ aṣọ tí ó nípọn.

22. Ó ṣe aṣọ títẹ́ fún ibùsùn rẹ̀;ẹwu dáradára àti eléṣè é àlùkò ni aṣọ rẹ̀

Ka pipe ipin Òwe 31