Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Òwe 31:23-31 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

23. A bọ̀wọ̀ fún ọkọ rẹ̀ ní ẹnu ibòde ìlúníbi tí ó ń jókòó láàrin àwọn àgbà ìlú

24. Ó ń ṣe àwọn aṣọ dáradára ó sì ń tà wọ́nó sì ń kó ọjà fún àwọn oníṣòwò

25. Agbára àti ọlá ni ó wò ọ́ láṣọó le fi ọjọ́ iwájú rẹ́rìn-ín.

26. A sọ̀rọ̀ pẹ̀lú ọgbọ́nìkọ́ni òtítọ́ sì ń bẹ létè e rẹ̀

27. Ó ń bojú tó gbogbo ètò ilé rẹ̀kì í sì í jẹ oúnjẹ ìmẹ́lẹ́

28. Àwọn ọmọ rẹ̀ dìde wọ́n sì pè é ní alábùkúnọkọ rẹ̀ pẹ̀lú ń gbóríyìn fún un

29. “Ọ̀pọ̀lọpọ̀ òbìnrin ní ń ṣe nǹkan ọlọ́láṣùgbọ́n ìwọ ju gbogbo wọn lọ”

30. Ojú dáradára a máa tan ni, ẹwà sì jẹ́ asánnítorí obìnrin tí ó bẹ̀rù Olúwa yẹ kí ó gba oríyìn

31. sì fún un ní èrè tí ó tọ́ sí ikí o sì jẹ́ kí iṣẹ́ rẹ̀ fún un ní ìyìn ní ẹnu ibòde ìlú.

Ka pipe ipin Òwe 31