22. Ó ṣe aṣọ títẹ́ fún ibùsùn rẹ̀;ẹwu dáradára àti eléṣè é àlùkò ni aṣọ rẹ̀
23. A bọ̀wọ̀ fún ọkọ rẹ̀ ní ẹnu ibòde ìlúníbi tí ó ń jókòó láàrin àwọn àgbà ìlú
24. Ó ń ṣe àwọn aṣọ dáradára ó sì ń tà wọ́nó sì ń kó ọjà fún àwọn oníṣòwò
25. Agbára àti ọlá ni ó wò ọ́ láṣọó le fi ọjọ́ iwájú rẹ́rìn-ín.
26. A sọ̀rọ̀ pẹ̀lú ọgbọ́nìkọ́ni òtítọ́ sì ń bẹ létè e rẹ̀
27. Ó ń bojú tó gbogbo ètò ilé rẹ̀kì í sì í jẹ oúnjẹ ìmẹ́lẹ́
28. Àwọn ọmọ rẹ̀ dìde wọ́n sì pè é ní alábùkúnọkọ rẹ̀ pẹ̀lú ń gbóríyìn fún un
29. “Ọ̀pọ̀lọpọ̀ òbìnrin ní ń ṣe nǹkan ọlọ́láṣùgbọ́n ìwọ ju gbogbo wọn lọ”
30. Ojú dáradára a máa tan ni, ẹwà sì jẹ́ asánnítorí obìnrin tí ó bẹ̀rù Olúwa yẹ kí ó gba oríyìn