20. ó la ọwọ́ rẹ̀ sí àwọn talákàó sì na ọwọ́ rẹ̀ sí àwọn aláìní.
21. Nígbà tí òjò dídì rọ̀, kò bẹ̀rù nítorí ìdílé rẹ̀nítorí gbogbo wọn ni ó wọ aṣọ tí ó nípọn.
22. Ó ṣe aṣọ títẹ́ fún ibùsùn rẹ̀;ẹwu dáradára àti eléṣè é àlùkò ni aṣọ rẹ̀
23. A bọ̀wọ̀ fún ọkọ rẹ̀ ní ẹnu ibòde ìlúníbi tí ó ń jókòó láàrin àwọn àgbà ìlú
24. Ó ń ṣe àwọn aṣọ dáradára ó sì ń tà wọ́nó sì ń kó ọjà fún àwọn oníṣòwò
25. Agbára àti ọlá ni ó wò ọ́ láṣọó le fi ọjọ́ iwájú rẹ́rìn-ín.