Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Òwe 31:2-7 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

2. “Ìwọ ọmọ mi, ìwọ ọmọ inú mi,ìwọ ọmọ ẹ̀jẹ̀ mi.

3. Má ṣe lo agbára rẹ lórí obìnrin,okun rẹ lórí àwọn tí ó pa àwọn ọba run.

4. “Kì í ṣe fún àwọn ọba, ìwọ Lémúélìkì í ṣe fún ọba láti mu ọtí wáìnìkì í ṣe fún alákòóso láti máa wá ọtí líle

5. Kí wọn má ba à mu ọtí yó kí wọn sì gbàgbé ohun tí òfin wíkí wọn sì fi ẹ̀tọ́ àwọn tí ara ń ni dù wọ́n

6. Fi ọtí líle fún àwọn tí ń ṣègbéwáìnì fún àwọn tí ó wà nínú ìrora;

7. Jẹ́ kí wọn mu ọtí kí wọn sì gbàgbé òsì wọnkí wọn má sì rántí òsì wọn mọ́.

Ka pipe ipin Òwe 31