Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Òwe 31:14-19 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

14. Ó dàbí ọkọ̀ ojú omi tí àwọn oníṣòwò;ó ń gbé oúnjẹ rẹ̀ wá láti ọ̀nà jínjìn

15. Ó dìde nígbà tí òkùnkùn sì kùn;ó ṣe oúnjẹ fún ìdílé rẹ̀àti ìpín oúnjẹ fún àwọn ìránṣẹ́-bìnrin rẹ̀.

16. Ó kíyèsí oko kan, ó sì rà á;nínú ohun tí ó ń wọlé fún un ó gbin àjàrà rẹ̀

17. Ó bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ rẹ̀ tagbáratagbáraApá rẹ̀ le koko fún iṣẹ́

18. Ó ríi pé òwò òun péfìtílà rẹ̀ kì í sìí kú ní òru

19. Ní ọwọ́ rẹ̀, ó di kẹ̀kẹ́ òwú múó sì na ọwọ́ rẹ̀ di ìrànwú mú

Ka pipe ipin Òwe 31