Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Òwe 31:1-7 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

1. Àwọn ọ̀rọ̀ ti Lémúélì ọ̀rọ̀ ìṣọtẹ́lẹ̀, tí ó jẹ́ pé mọ̀mọ́ rẹ̀ ló kọ ọ́:

2. “Ìwọ ọmọ mi, ìwọ ọmọ inú mi,ìwọ ọmọ ẹ̀jẹ̀ mi.

3. Má ṣe lo agbára rẹ lórí obìnrin,okun rẹ lórí àwọn tí ó pa àwọn ọba run.

4. “Kì í ṣe fún àwọn ọba, ìwọ Lémúélìkì í ṣe fún ọba láti mu ọtí wáìnìkì í ṣe fún alákòóso láti máa wá ọtí líle

5. Kí wọn má ba à mu ọtí yó kí wọn sì gbàgbé ohun tí òfin wíkí wọn sì fi ẹ̀tọ́ àwọn tí ara ń ni dù wọ́n

6. Fi ọtí líle fún àwọn tí ń ṣègbéwáìnì fún àwọn tí ó wà nínú ìrora;

7. Jẹ́ kí wọn mu ọtí kí wọn sì gbàgbé òsì wọnkí wọn má sì rántí òsì wọn mọ́.

Ka pipe ipin Òwe 31