Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Òwe 30:18-28 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

18. “Àwọn nǹkan mẹ́ta wà tí ó jẹ́ ìyàlẹ́nu fún mi,mẹ́rin tí kò yé mi:

19. Ipa idì ní òfuurufúipa ejò lórí àpátaipa ọkọ̀ ojú omi lójú agbami òkunàti ipa ọ̀nà ọkùnrin tí ó mú wúndíá lọ́wọ́.

20. “Èyí ni ọ̀nà alágbérè obìnrinó jẹun o sì nu ẹnu rẹ̀ó sì wí pé, N kò ṣe ohunkóhun tí kò tọ́.

21. “Lábẹ́ nǹkan mẹ́ta ni ile ayé ti ń wárìrìlábẹ́ ohun mẹ́rin ni kò ti lè mí fín ín.

22. Ìránṣẹ́ tí ó di Ọbaaláìgbọ́n tí ó ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ oúnjẹ́

23. Obìnrin tí gbogbo ènìyàn kórìíra tí ó sì wá lọ́kọìránṣẹ́bìnrin tí ó gbọkọ mọ́ ọ̀gá rẹ̀ lọ́wọ́.

24. “Àwọn ohun mẹ́rin ló kéré láyésíbẹ̀ wọ́n gbọ́n gidigidi;

25. Àwọn èrà jẹ́ ẹ̀dá tí ó ní agbára díẹ̀síbẹ̀ wọ́n kó oúnjẹ wọn pamọ́ ní àsìkò òjò

26. Ehoro jẹ́ ẹ̀dá tí kò ní agbára púpọ̀ṣíbẹ̀ wọ́n ń ṣe ilé wọn sí ibi ihò àpáta;

27. Eṣú kò ní ọbaṣíbẹ̀ wọ́n ń jáde lọ papọ̀ ní ọ̀wọ̀ọ̀wọ́

28. a lè fi ọwọ́ mú aláǹgbáṣíbẹ̀ a ń rí i ní ààfin ọba.

Ka pipe ipin Òwe 30