Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Òwe 3:26-35 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

26. Nítorí Olúwa yóò jẹ́ ìgbẹ́kẹ̀lé rẹkì yóò sì jẹ́ kí ẹsẹ̀ rẹ bọ́ sínú pàkúté.

27. Má ṣe fa ọwọ́ ire sẹ́yìn kúrò lọ́dọ̀ àwọn tí ó tọ́ sí,nígbà tí ó bá wà ní ìkápá rẹ láti ṣe ohun kan.

28. Má ṣe wí fún aládùúgbò rẹ pé,“Padà wá nígbà tó ṣe díẹ̀; ó fún ọ lọ́lá”nígbà tí o ní i pẹ̀lú rẹ nísinsin yìí.

29. Má ṣe pète ohun búburú fún aládùúgbò rẹ,ti o gbé nítòsí rẹ, tí ó sì fọkàn tán ọ.

30. Má ṣe fẹ̀ṣùn kan ènìyàn láì-ní-ìdínígbà tí kò ṣe ọ́ ní ibi kankan rárá.

31. Má ṣe ṣe ìlara ènìyàn jàgídíjàgantàbí kí o yàn láti rìn ní ọ̀nà rẹ̀,

32. Nítorí Olúwa kórìíra ènìyàn aláyìídáyidàṣùgbọ́n a máa fọkàn tán ẹni dídúró ṣinṣin.

33. Ègún Olúwa ń bẹ lórí ilé ènìyàn búburú,ṣùgbọ́n ó bùkún fún ilé olódodo

34. Ó fi àwọn oníyẹ̀yẹ́ ṣe yẹ̀yẹ́Ṣùgbọ́n ó fi oore ọ̀fẹ́ fún onírẹ̀lẹ̀

35. ọlọ́gbọ́n jogún iyìṢùgbọ́n àwọn aláìgbọ́n ni ó dójú tì.

Ka pipe ipin Òwe 3