Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Òwe 28:25-28 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

25. Ọ̀kanjúà ènìyàn a máa dá ìjà sílẹ̀,ṣùgbọ́n ẹni tí ó bá gbẹ́kẹ̀lé Olúwa yóò gbilẹ̀.

26. Ẹni tí ó gbẹ́kẹ̀lé ara rẹ̀ jẹ́ aláìgbọ́nṣùgbọ́n ẹni tí ń rìn nínú ọgbọ́n wà láìléwu.

27. Ẹni tí ó ń fifún talákà kì yóò ṣe aláìní ohunkóhunṣùgbọ́n ẹni tí ó di ojú rẹ̀ sí wọn gba ọ̀pọ̀lọpọ̀ ègún.

28. Nígbà tí ènìyàn búburú bá dórí ìjọba, àwọn ènìyàn a na pápá bora;ṣùgbọ́n nígbà tí ènìyàn búburú bá ṣègbé,àwọn olódodo ń gbilẹ̀ síi.

Ka pipe ipin Òwe 28