Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Òwe 28:18-28 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

18. Ẹni tí ìrìn rẹ̀ kò ní àbùkù wà láìléwuṣùgbọ́n ẹni tí ọ̀nà rẹ̀ jẹ́ ayípadà yóò ṣubú lójijì.

19. Ẹni tí ó bá ro ilẹ̀ rẹ̀ yóò ní oúnjẹ lọ́pọ̀lọpọ̀ṣùgbọ́n ẹni tí ń lé ohun aṣán yóò kún fún òsì.

20. Olóòótọ́ ènìyàn yóò rí ìbùkún gbà gan anṣùgbọ́n ẹni tí ojú ń kán láti di ọlọ́rọ̀ kì yóò lọ, láìjìyà.

21. Ojúṣááj ú ṣíṣe kò dáraṣíbẹ̀ ènìyàn kan ń ṣẹ̀ nítorí òkèlè oúnjẹ kan.

22. Ahun ń sáré àti làkò sì funra pé òsì dúró de òun.

23. Ẹni tí ó bá ènìyàn kan wí yóò rí ojú rere síi nígbẹ̀yìnju ẹni tí ó ní ètè ẹ̀tàn lọ.

24. Ẹni tí ó ja baba tàbí ìyá rẹ̀ lólètí ó sì wí pé “Kì í ṣe ẹ̀ṣẹ̀”irú kan ni òun àti ẹni tí ń panírun.

25. Ọ̀kanjúà ènìyàn a máa dá ìjà sílẹ̀,ṣùgbọ́n ẹni tí ó bá gbẹ́kẹ̀lé Olúwa yóò gbilẹ̀.

26. Ẹni tí ó gbẹ́kẹ̀lé ara rẹ̀ jẹ́ aláìgbọ́nṣùgbọ́n ẹni tí ń rìn nínú ọgbọ́n wà láìléwu.

27. Ẹni tí ó ń fifún talákà kì yóò ṣe aláìní ohunkóhunṣùgbọ́n ẹni tí ó di ojú rẹ̀ sí wọn gba ọ̀pọ̀lọpọ̀ ègún.

28. Nígbà tí ènìyàn búburú bá dórí ìjọba, àwọn ènìyàn a na pápá bora;ṣùgbọ́n nígbà tí ènìyàn búburú bá ṣègbé,àwọn olódodo ń gbilẹ̀ síi.

Ka pipe ipin Òwe 28