Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Òwe 28:1-9 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

1. Ènìyàn búburú ń sá bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ẹnìkan kò lé eṣùgbọ́n olódodo láyà bí i kìnnìún.

2. Nígbà tí orílẹ̀ èdè bá ní orí kunkun, àwọn ọba rẹ̀ a máa pọ̀ṣùgbọ́n olóye àti onímọ̀ a máa pa òfin mọ́

3. ọba tí ó ni àwọn talákà láradàbí àgbàrá òjò tí ó ń gbá gbogbo ẹ̀gbìn lọ.

4. Àwọn tí ó kọ òfin sílẹ̀ a máa gbóríyìn fún ènìyàn búburúṣùgbọ́n àwọn tí ó pa òfin mọ́ kọjú ìjà sí ènìyàn búburú.

5. Òye ìdájọ́ òdodo kò yé àwọn ẹni ibiṣùgbọ́n ó yé àwọn tí ń wá Olúwa dáradára.

6. Ó sàn láti jẹ́ talákà tí ìrìn rẹ̀ jẹ́ aláìlábùkùju ọlọ́rọ̀ tí ọ̀nà rẹ̀ rí pálapàla.

7. Ẹni tí ó pa òfin mọ́ jẹ́ olóye ọmọṣùgbọ́n ẹni tí ó bá jẹgúdújẹrá kẹ́gbẹ́ dójú ti baba rẹ̀.

8. Ẹni tí ó mú ọrọ̀ rẹ̀ di púpọ̀ nípa èrè àjẹjùń kó o jọ fún ẹlòmìíràn, tí yóò ní àánú àwọn talákà.

9. Bí ẹnikẹ́ni bá kọ etí ikún sí òfin,kódà àdúrà rẹ̀ jẹ́ ìríra.

Ka pipe ipin Òwe 28