Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Òwe 26:10-22 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

10. Bí tafàtafà ti ń ṣe ni léṣe lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kanni ẹni tí ó gba aṣiwèrè síṣẹ́ tàbí ẹni tí ń kọjá lọ.

11. Bí ajá ti í padà sí èébì rẹ̀bẹ́ẹ̀ ni aṣiwèrè tún ń hu ìwà òmùgọ̀ rẹ̀.

12. Ǹjẹ́ o rí ènìyàn tí ó jẹ́ ọlọ́gbọ́n ní ojú ara rẹ̀?Ìrètí ń bẹ fún aláìgbọ́n ènìyàn jù ú lọ.

13. Ọ̀lẹ wí pé: “Kìnnìún wà lójú ọ̀nàkìnnìún búburú ń ké ní ojú ọ̀nà.”

14. Bí ilẹ̀kùn ti ń yí lórí ìsolẹ̀kùn rẹ̀,bẹ́ẹ̀ ni ọ̀lẹ ń yí lórí ibùsùn rẹ̀.

15. Ọ̀lẹ ki ọwọ́ rẹ̀ bọ inú àwo oúnjẹ,ó lẹ débi pé kò le è mú u padà wá sí ẹnu rẹ̀.

16. Ọ̀lẹ gbọ́n ní ojú ara rẹ̀,ju ènìyàn méje tí wọ́n le è fún un ní ìdáhùn ọlọgbọ́n.

17. Bí ènìyàn tí ó di ajá ní etí múni ẹni tí ń kọjá lọ tí ó dá sí ọ̀rọ̀ ìjà tí kì í ṣe tirẹ̀.

18. Bí i asínwín ti ń juọfà àti ọfà tí ń ṣekú pani

19. ni ènìyàn tí ń tan aládùúgbò rẹ̀ jẹtí ó sì wí pé, “Àwàdà lásán ni mo ń ṣe.”

20. Láìsí igi, iná yóò kúláì sí ọ̀rọ̀ ẹ̀yìn, ìjà máa ń parí.

21. Bí èédú ti rí sí ẹyin iná, igi fún iná,bẹ́ẹ̀ ni ènìyàn oníjà fún ìjà dídá sílẹ̀.

22. Ọ̀rọ̀ ẹni tí ń sọ̀rọ̀ ẹ̀yìn dàbí àṣàyàn òkèlèwọn a máa sọ̀kalẹ̀ lọ sí akínyẹmí ara.

Ka pipe ipin Òwe 26