Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Òwe 26:1-14 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

1. Bí òjò dídì tàbí òjò ní ìgbà ìkórèọlá kò yẹ aláìgbọ́n ènìyàn.

2. Bí ológoṣẹ́ tí ń sí kiri tàbí alápáǹdẹ̀dẹ̀ tí ń rá bàbàÈpè kò le è mọ́ ẹni tí kò ṣiṣẹ́ èpèÈpè kì í jani bí a kò bá ṣiṣẹ́ èpè.

3. Lagbà fún ẹṣin, ìjánu fún kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́àti pàṣán fún ẹ̀yìn aṣiwèrè.

4. Má ṣe dá aláìgbọ́n lóhùn gẹ́gẹ́ bí ìwà òmùgọ̀ rẹ̀àìṣe bẹ́ẹ̀ ìwọ pẹ̀lú yóò dàbí i rẹ̀.

5. Dá aláìgbọ́n lóhùn gẹ́gẹ́ bí ìwà òmùgọ̀ rẹ̀àìṣe bẹ́ẹ̀ yóò dàbí ọlọ́gbọ́n lójú ara rẹ̀.

6. Bí ìgbà tí ènìyàn gé ẹsẹ̀ ara rẹ̀ tàbí mú ìwà ipáni kí a ránṣẹ́ nípaṣẹ̀ aṣiwèrè.

7. Bí ẹsẹ̀ arọ tí ó ń mi dirodironi òwe lẹ́nu àṣiwèrè.

8. Bí ìgbà tí a so òkúta mọ́ okùn títani fífún aláìgbọ́n ní ọlá.

9. Bí ẹ̀gún èṣùṣú lọ́wọ́ ọ̀mùtíni òwe lẹ́nu aláìgbọ́n.

10. Bí tafàtafà ti ń ṣe ni léṣe lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kanni ẹni tí ó gba aṣiwèrè síṣẹ́ tàbí ẹni tí ń kọjá lọ.

11. Bí ajá ti í padà sí èébì rẹ̀bẹ́ẹ̀ ni aṣiwèrè tún ń hu ìwà òmùgọ̀ rẹ̀.

12. Ǹjẹ́ o rí ènìyàn tí ó jẹ́ ọlọ́gbọ́n ní ojú ara rẹ̀?Ìrètí ń bẹ fún aláìgbọ́n ènìyàn jù ú lọ.

13. Ọ̀lẹ wí pé: “Kìnnìún wà lójú ọ̀nàkìnnìún búburú ń ké ní ojú ọ̀nà.”

14. Bí ilẹ̀kùn ti ń yí lórí ìsolẹ̀kùn rẹ̀,bẹ́ẹ̀ ni ọ̀lẹ ń yí lórí ibùsùn rẹ̀.

Ka pipe ipin Òwe 26