Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Òwe 23:30-34 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

30. Àwọn tí ó dúró pẹ́ níbi ọtí-wáìnì;àwọn tí ń lọ láti dán ọtí wáìnì àdàlú wò.

31. Ìwọ má ṣe wò ọtí-wáìnì nígbà tí ó pọ́n,nígbà tí ó bá ń fi àwọ̀ rẹ̀ hàn nínú ago,tí a gbé e mì, tí ó ń dùn.

32. Níkẹyìn òun á bunisán bí ejò,a sì bunijẹ bí i paramọ́lẹ̀.

33. Ojú rẹ yóò wò àwọn àjèjì obìnrin,àyà rẹ yóò sì sọ̀rọ àyídáyidà.

34. Nítòótọ́, ìwọ ó dàbí ẹni tí ó dùbúlẹ̀ ní àárin òkun,tàbí ẹni tí ó dúbúlẹ̀ lókè-ọkọ̀.

Ka pipe ipin Òwe 23