Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Òwe 23:22-35 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

22. Fetí sí ti baba rẹ tí ó bí ọ,má sì ṣe gan ìyá rẹ, nígbà tí o bá gbó

23. Ra òtítọ́, kí o má sì ṣe tà á;ra ọgbọ́n pẹ̀lú àti ẹ̀kọ́, àti òye.

24. Baba olódodo ni yóò yọ̀ gidigidi:ẹni tí ó sì bí ọmọ ọlọ́gbọ́n,yóò ní ayọ̀ nínú rẹ̀.

25. Jẹ́ kí bàbá rẹ àti ìyá rẹ ó yọ̀,sì jẹ́ kí inú ẹni tí ó bí ọ dùn.

26. Ọmọ mi, fi àyà rẹ fún mi,kí o sì jẹ́ kí ojú rẹ ní inú-dídùn sí ọ̀nà mi.

27. Nítorí pé panṣágà-obìnrin ọ̀gbun jínjìn ni;àti àjèjì-obìnrin kànga híhá ni.

28. Òun á sì ba ní bùba bí olè,a sì sọ àwọn olùrékọjá di púpọ̀ nínú àwọn ènìyàn.

29. Ta ni ó ni òsì? Ta ni ó ni ìbànújẹ́?Ta ni ó ni ìjà? Ta ni ó ni aṣọ̀? Ta ni ó ni ọgbẹ́ láìnídìí?

30. Àwọn tí ó dúró pẹ́ níbi ọtí-wáìnì;àwọn tí ń lọ láti dán ọtí wáìnì àdàlú wò.

31. Ìwọ má ṣe wò ọtí-wáìnì nígbà tí ó pọ́n,nígbà tí ó bá ń fi àwọ̀ rẹ̀ hàn nínú ago,tí a gbé e mì, tí ó ń dùn.

32. Níkẹyìn òun á bunisán bí ejò,a sì bunijẹ bí i paramọ́lẹ̀.

33. Ojú rẹ yóò wò àwọn àjèjì obìnrin,àyà rẹ yóò sì sọ̀rọ àyídáyidà.

34. Nítòótọ́, ìwọ ó dàbí ẹni tí ó dùbúlẹ̀ ní àárin òkun,tàbí ẹni tí ó dúbúlẹ̀ lókè-ọkọ̀.

35. Ìwọ ó sì wí pé, “Wọ́n lù mí; kò dùn mí;wọ́n lù mí, èmi kò sì mọ̀:nígbàwo ni èmi ó jí?Èmi ó tún máa wá òmíràn láti mu.”

Ka pipe ipin Òwe 23