Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Òwe 23:2-6 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

2. Ìwọ a sì fi ọ̀bẹ lé ara rẹ ní ọ̀fun,bí ìwọ bá jẹ́ òkúndùn ènìyàn.

3. Má ṣe fẹ́ oúnjẹ-dídùn rẹ̀:nítorí pé oúnjẹ ẹ̀tàn ni.

4. Má ṣe ṣe làálàá láti lọ́rọ̀:síwọ́ kúrò nínú ọgbọ́n ara rẹ.

5. Ìwọ ó ha fi ojú rẹ lépa ohun tí kò sí?Nítorí tí ọ̀rọ̀ hu ìyẹ́-apá fún ara rẹ̀,ó sì ń fò bí idì ní ojú ọ̀run.

6. Má ṣe jẹ oúnjẹ olójú búburú,bẹ́ẹ̀ ni kí o má sì ṣe fẹ́ oúnjẹ-dídùn rẹ̀.

Ka pipe ipin Òwe 23