Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Òwe 23:16-20 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

16. Inú mi yóò sì dùn nígbà tí ètè rẹ̀ bá ń sọ̀rọ̀ títọ́.

17. Má ṣe jẹ́ kí àyà rẹ ó ṣe ìlara sí àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀,ṣùgbọ́n kí ìwọ ó wà ní ìbẹ̀rù Olúwa,ní ọjọ́ gbogbo.

18. Nítorí pé ìkẹyìn ń bẹ nítòótọ́;ìrètí rẹ̀ kì yóò sì gé kúrò.

19. Gbọ́, ìwọ ọmọ mi, kí o sì gbọ́n,kí o sì máa tọ́ àyà rẹ sí ọ̀nà títọ́.

20. Má ṣe wà nínú àwọn ọ̀mùtí;àti àwọn wọ̀bìà alájẹkì ọ̀jẹun;

Ka pipe ipin Òwe 23